18. Ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru wọn: ṣugbọn ki iwọ ki o ranti daradara ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Farao, ati si gbogbo Egipti;
19. Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà.
20. Pẹlupẹlu OLUWA Ọlọrun rẹ yio rán agbọ́n sinu wọn, titi awọn ti o kù, ti nwọn si fi ara wọn pamọ́ fun ọ yio fi run.
21. Ki iwọ ki o máṣe fòya wọn: nitoriti OLUWA Ọlọrun rẹ mbẹ lãrin rẹ, Ọlọrun ti o tobi ti o si lẹrù.
22. OLUWA Ọlọrun rẹ yio tì awọn orilẹ-ède na jade diẹdiẹ niwaju rẹ: ki iwọ ki o máṣe run wọn tán lẹ̃kan, ki ẹranko igbẹ́ ki o má ba pọ̀ si ọ.
23. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi wọn lé ọ lọwọ, yio si fi iparun nla pa wọn run, titi nwọn o fi run.
24. On o si fi awọn ọba wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si pa orukọ wọn run kuro labẹ ọrun: kò sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ, titi iwọ o fi run wọn tán.
25. Ere finfin oriṣa wọn ni ki ẹnyin ki o fi iná jó: iwọ kò gbọdọ ṣe ojukokoro fadakà tabi wurà ti mbẹ lara wọn, bẹ̃ni ki o máṣe mú u fun ara rẹ, ki o má ba di idẹkùn fun ọ; nitoripe ohun irira ni si OLUWA Ọlọrun rẹ:
26. Bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ mú ohun irira wá sinu ile rẹ, ki iwọ ki o má ba di ẹni ifibú bi rẹ̀: ṣugbọn ki iwọ ki o korira rẹ̀ patapata, ki iwọ ki o si kà a si ohun irira patapata; nitoripe ohun ìyasọtọ ni.