10. Ti o si nsan a pada fun awọn ti o korira rẹ̀ li oju wọn, lati run wọn: on ki yio jafara fun ẹniti o korira rẹ̀, on o san a fun u loju rẹ̀.
11. Nitorina ki iwọ ki o pa ofin, ati ìlana, ati idajọ mọ́, ti mo palaṣẹ fun ọ li oni, lati ma ṣe wọn.
12. Yio si ṣe, nitoriti ẹnyin fetisi idajọ wọnyi, ti ẹ si npa wọn mọ́, ti ẹ si nṣe wọn, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio ma pa majẹmu ati ãnu mọ́ fun ọ, ti o ti bura fun awọn baba rẹ:
13. On o si fẹ́ ọ, yio si bukún ọ, yio si mu ọ bisi i: on o si bukún ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ọkà rẹ, ati ọti-waini rẹ, ati oróro rẹ, ibisi malu rẹ, ati awọn ọmọ agbo-agutan rẹ, ni ilẹ na ti o ti bura fun awọn baba rẹ lati fi fun ọ.
14. Iwọ o jẹ́ ẹni ibukún jù gbogbo enia lọ: ki yio sí akọ tabi abo ninu nyin ti yio yàgan, tabi ninu ohunọ̀sin nyin.
15. OLUWA yio si gbà àrun gbogbo kuro lọdọ rẹ, ki yio si fi ọkan ninu àrun buburu Egipti, ti iwọ mọ̀, si ọ lara, ṣugbọn on o fi wọn lé ara gbogbo awọn ti o korira rẹ.
16. Iwọ o si run gbogbo awọn enia ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio fi fun ọ; oju rẹ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn: bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn awọn oriṣa wọn; nitoripe idẹkùn li eyinì yio jẹ́ fun ọ.
17. Bi iwọ ba wi li ọkàn rẹ pe, Awọn orilẹ-ède wọnyi pọ̀ jù mi lọ; bawo li emi o ṣe le lé wọn jade?
18. Ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru wọn: ṣugbọn ki iwọ ki o ranti daradara ohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ṣe si Farao, ati si gbogbo Egipti;
19. Idanwò nla ti oju rẹ ri, ati àmi, ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ́ agbara, ati ninà apa, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi mú ọ jade: bẹ̃ni OLUWA Ọlọrun rẹ yio ṣe si gbogbo awọn enia na ẹ̀ru ẹniti iwọ mbà.
20. Pẹlupẹlu OLUWA Ọlọrun rẹ yio rán agbọ́n sinu wọn, titi awọn ti o kù, ti nwọn si fi ara wọn pamọ́ fun ọ yio fi run.