Deu 4:26-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

26. Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata.

27. OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si.

28. Nibẹ̀ li ẹnyin o si ma sìn oriṣa, iṣẹ ọwọ́ enia, igi ati okuta, ti kò riran, ti kò si gbọran, ti kò jẹun, ti kò si gbõrun.

29. Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a.

30. Nigbati iwọ ba mbẹ ninu ipọnju, ti nkan gbogbo wọnyi ba si bá ọ, nikẹhin ọjọ́, bi iwọ ba yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́:

31. Nitoripe Ọlọrun alãnu ni OLUWA Ọlọrun rẹ; on ki yio kọ̀ ọ silẹ, bẹ̃ni ki yio run ọ, bẹ̃ni ki yio gbagbé majẹmu awọn baba rẹ, ti o ti bura fun wọn.

32. Njẹ bère nisisiyi niti ọjọ́ igbãni, ti o ti mbẹ ṣaju rẹ, lati ọjọ́ ti Ọlọrun ti dá enia sori ilẹ, ki o si bère lati ìha ọrun kini dé ìha keji, bi irú nkan bi ohun nla yi wà rí, tabi bi a gburó irú rẹ̀ rí?

33. Awọn enia kan ha gbọ́ ohùn Ọlọrun rí ki o ma bá wọn sọ̀rọ lati ãrin iná wá, bi iwọ ti gbọ́, ti o si wà lãye?

34. Tabi Ọlọrun ha dán a wò rí lati lọ mú orilẹ-ède kan fun ara rẹ̀ lati ãrin orilẹ-ède miran wá, nipa idanwò, nipa àmi, ati nipa iṣẹ-iyanu, ati nipa ogun, ati nipa ọwọ́ agbara, ati nipa ninà apa, ati nipa ẹ̀ru nla, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun nyin ṣe fun nyin ni Egipti ni oju nyin?

35. Iwọ li a fihàn, ki iwọ ki o le mọ̀ pe OLUWA on li Ọlọrun; kò sí ẹlomiran lẹhin rẹ̀.

36. O mu ọ gbọ́ ohùn rẹ̀ lati ọrun wá, ki o le kọ́ ọ: ati lori ilẹ aiye o fi iná nla rẹ̀ hàn ọ; iwọ si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀ lati ãrin iná wá.

37. Ati nitoriti o fẹ́ awọn baba rẹ, nitorina li o ṣe yàn irú-ọmọ wọn lẹhin wọn, o si fi agbara nla rẹ̀ mú ọ lati Egipti jade wá li oju rẹ̀;

38. Lati lé awọn orilẹ-ède jade kuro niwaju rẹ, ti o tobi, ti o si lagbara jù ọ lọ, lati mú ọ wọle, lati fi ilẹ wọn fun ọ ni iní, bi o ti ri li oni yi.

Deu 4