Deu 4:20-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Ṣugbọn OLUWA ti gbà nyin, o si mú nyin lati ileru irin, lati Egipti jade wá, lati ma jẹ́ enia iní fun u, bi ẹnyin ti ri li oni yi.

21. OLUWA si binu si mi nitori nyin, o si bura pe, emi ki yio gòke Jordani, ati pe emi ki yio wọ̀ inu ilẹ rere nì, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni ilẹ-iní.

22. Ṣugbọn emi o kú ni ilẹ yi, emi ki yio gòke odò Jordani: ṣugbọn ẹnyin o gòke ẹnyin o si gbà ilẹ rere na.

23. Ẹ ma ṣọra nyin, ki ẹnyin má ba gbagbé majẹmu OLUWA Ọlọrun nyin, ti o ti bá nyin dá, ki ẹnyin má ba lọ ṣe ere finfin fun ara nyin, tabi aworán ohunkohun ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti kọ̀ fun ọ.

24. Nitori OLUWA Ọlọrun rẹ ajonirun iná ni, Ọlọrun owú.

25. Nigbati iwọ ba bi ọmọ, ati ọmọ ọmọ, ti ẹ ba si pẹ ni ilẹ na, ti ẹ si bà ara nyin jẹ́, ti ẹ si ṣe ere finfin, tabi aworán ohunkohun, ti ẹ si ṣe eyiti o buru li oju OLUWA Ọlọrun rẹ lati mu u binu:

26. Mo pè ọrun ati aiye jẹri si nyin li oni, pe lọ́gan li ẹnyin o run kuro patapata ni ilẹ na nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a; ẹnyin ki yio lò ọjọ́ nyin pẹ ninu rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin o si run patapata.

27. OLUWA yio si tú nyin ká ninu awọn orilẹ-ède, diẹ ni ẹnyin o si kù ni iye ninu awọn orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio darí nyin si.

28. Nibẹ̀ li ẹnyin o si ma sìn oriṣa, iṣẹ ọwọ́ enia, igi ati okuta, ti kò riran, ti kò si gbọran, ti kò jẹun, ti kò si gbõrun.

29. Ṣugbọn bi iwọ ba wá OLUWA Ọlọrun rẹ lati ibẹ̀ lọ, iwọ o ri i, bi iwọ ba fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ wá a.

30. Nigbati iwọ ba mbẹ ninu ipọnju, ti nkan gbogbo wọnyi ba si bá ọ, nikẹhin ọjọ́, bi iwọ ba yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ, ti iwọ ba si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́:

Deu 4