4. Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu.
5. O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀.
6. Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn.
7. Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀.
8. Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba;
9. Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́.
10. Nwọn o ma kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli li ofin rẹ: nwọn o ma mú turari wá siwaju rẹ, ati ọ̀tọtọ ẹbọ sisun sori pẹpẹ rẹ.
11. OLUWA, busi ohun-iní rẹ̀, ki o si tẹwọgbà iṣẹ ọwọ́ rẹ̀: lù ẹgbẹ́ awọn ti o dide si i, ati ti awọn ti o korira rẹ̀, ki nwọn ki o máṣe dide mọ́.
12. Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀.
13. Ati niti Josefu o wipe, Ibukún OLUWA ni ilẹ rẹ̀, fun ohun iyebiye ọrun, fun ìri, ati fun ibú ti o ba nisalẹ,
14. Ati fun eso iyebiye ti õrùn múwa, ati fun ohun iyebiye ti ndàgba li oṣoṣù,
15. Ati fun ohun pàtaki okenla igbãni, ati fun ohun iyebiye òke aiyeraiye,
16. Ati fun ohun iyebiye aiye ati ẹkún rẹ̀, ati fun ifẹ́ inurere ẹniti o gbé inu igbẹ́: jẹ ki ibukún ki o wá si ori Josefu, ati si atari ẹniti a yàsọtọ lãrin awọn arakunrin rẹ̀.
17. Akọ́bi akọmalu rẹ̀, tirẹ̀ li ọlánla; iwo rẹ̀ iwo agbanrere ni: on ni yio fi tì awọn enia, gbogbo wọn, ani opin ilẹ: awọn si ni ẹgbẹgbãrun Efraimu, awọn si ni ẹgbẹgbẹrun Manasse.
18. Ati niti Sebuluni o wipe, Sebuluni, ma yọ̀ ni ijade rẹ; ati Issakari, ninu agọ́ rẹ.
19. Nwọn o pè awọn enia na sori òke; nibẹ̀ ni nwọn o ru ẹbọ ododo: nitoripe nwọn o ma mu ninu ọ̀pọlọpọ okun, ati ninu iṣura ti a pamọ́ ninu iyanrin.
20. Ati niti Gadi o wipe, Ibukún ni fun ẹniti o mu Gadi gbilẹ: o ba bi abo-kiniun, o si fà apa ya, ani atari.
21. O si yàn apá ikini fun ara rẹ̀, nitoripe nibẹ̀ li a fi ipín olofin pamọ́ si; o si wá pẹlu awọn olori enia na, o si mú ododo OLUWA ṣẹ, ati idajọ rẹ̀ pẹlu Israeli.