23. Ati niti Naftali o wipe, Iwọ Naftali, ti ojurere tẹ́lọrùn, ti o si kún fun ibukún OLUWA: gbà ìha ìwọ-õrùn ati gusù.
24. Ati niti Aṣeri o wipe, Ibukún ọmọ niti Aṣeri; ki on ki o si jẹ́ itẹwọgba fun awọn arakunrin rẹ̀, ki on ki o si ma rì ẹsẹ̀ rẹ̀ sinu oróro.
25. Bàta rẹ yio jasi irin ati idẹ; ati bi ọjọ́ rẹ, bẹ̃li agbara rẹ yio ri.
26. Kò sí ẹniti o dabi Ọlọrun, iwọ Jeṣuruni, ti ngùn ọrun fun iranlọwọ rẹ, ati ninu ọlanla rẹ̀ li oju-ọrun.
27. Ọlọrun aiyeraiye ni ibugbé rẹ, ati nisalẹ li apa aiyeraiye wà: on si tì ọtá kuro niwaju rẹ, o si wipe, Ma parun.
28. Israeli si joko li alafia, orisun Jakobu nikan, ni ilẹ ọkà ati ti ọti-waini; pẹlupẹlu ọrun rẹ̀ nsẹ̀ ìri silẹ.
29. Alafia ni fun iwọ, Israeli: tali o dabi rẹ, iwọ enia ti a ti ọwọ́ OLUWA gbàla, asà iranlọwọ rẹ, ati ẹniti iṣe idà ọlanla rẹ! awọn ọtá rẹ yio si tẹriba fun ọ; iwọ o si ma tẹ̀ ibi giga wọn mọlẹ.