Deu 33:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EYI si ni ire, ti Mose enia Ọlọrun su fun awọn ọmọ Israeli ki o to kú.

2. O si wipe, OLUWA ti Sinai wá, o si yọ si wọn lati Seiri wá; o tàn imọlẹ jade lati òke Parani wá, o ti ọdọ ẹgbẹgbãrun awọn mimọ́ wá: lati ọwọ́ ọtún rẹ̀ li ofin kan amubĩná ti jade fun wọn wá.

3. Nitõtọ, o fẹ́ awọn enia na; gbogbo awọn enia mimọ́ rẹ̀ wà li ọwọ́ rẹ. Nwọn si joko li ẹsẹ̀ rẹ; olukuluku ni yio gbà ninu ọ̀rọ rẹ.

4. Mose fi ofin kan lelẹ li aṣẹ fun wa, iní ti ijọ enia Jakobu.

5. O si jẹ́ ọba ni Jeṣuruni, nigbati olori awọn enia, awọn ẹ̀ya Israeli pejọ pọ̀.

6. Ki Reubeni ki o yè, ki o máṣe kú; ki enia rẹ̀ ki o máṣe mọniwọn.

7. Eyi si ni ti Judah: o si wipe, OLUWA, gbọ́ ohùn Judah, ki o si mú u tọ̀ awọn enia rẹ̀ wá: ki ọwọ́ rẹ̀ ki o to fun u; ki iwọ ki o si ṣe iranlọwọ fun u lọwọ awọn ọtá rẹ̀.

8. Ati niti Lefi o wipe, Jẹ ki Tummimu ati Urimu rẹ ki o wà pẹlu ẹni mimọ́ rẹ, ẹniti iwọ danwò ni Massa, ati ẹniti iwọ bá jà li omi Meriba;

9. Ẹniti o wi niti baba rẹ̀, ati niti iya rẹ̀ pe, Emi kò ri i; bẹ̃ni kò si jẹwọ awọn arakunrin rẹ̀, bẹ̃ni kò si mọ̀ awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti nwọn kiyesi ọ̀rọ rẹ, nwọn si pa majẹmu rẹ mọ́.

10. Nwọn o ma kọ́ Jakobu ni idajọ rẹ, ati Israeli li ofin rẹ: nwọn o ma mú turari wá siwaju rẹ, ati ọ̀tọtọ ẹbọ sisun sori pẹpẹ rẹ.

11. OLUWA, busi ohun-iní rẹ̀, ki o si tẹwọgbà iṣẹ ọwọ́ rẹ̀: lù ẹgbẹ́ awọn ti o dide si i, ati ti awọn ti o korira rẹ̀, ki nwọn ki o máṣe dide mọ́.

12. Ati niti Benjamini o wipe, Olufẹ OLUWA yio ma gbé li alafia lọdọ rẹ̀; on a ma bò o li ọjọ́ gbogbo, on a si ma gbé lãrin ejika rẹ̀.

Deu 33