36. Nitoripe OLUWA yio ṣe idajọ awọn enia rẹ̀, yio si kãnu awọn iranṣẹ rẹ̀; nigbati o ba ri pe agbara wọn lọ tán, ti kò si sí ẹnikan ti a sé mọ́, tabi ti o kù.
37. On o si wipe, Nibo li oriṣa wọn gbé wà, apata ti nwọn gbẹkẹle:
38. Ti o ti jẹ ọrá ẹbọ wọn, ti o ti mu ọti-waini ẹbọ ohunmimu wọn? jẹ ki nwọn dide ki nwọn si ràn nyin lọwọ, ki nwọn ṣe àbo nyin.
39. Wò o nisisiyi pe Emi, ani Emi ni, kò si sí ọlọrun pẹlu mi: mo pa, mo si sọ di ãye; mo ṣalọgbẹ, mo si mu jiná; kò si sí ẹnikan ti o le gbà silẹ li ọwọ́ mi.
40. Nitoripe mo gbé ọwọ́ mi soke ọrun, mo si wipe, Bi Emi ti wà titilai.
41. Bi mo ba si pọ́n idà didan mi, ti mo ba si fi ọwọ́ mi lé idajọ; emi o san ẹsan fun awọn ọtá mi, emi o radi i fun awọn ti o korira mi.
42. Emi o mu ọfà mi rin fun ẹ̀jẹ, idà mi o si jẹ ẹran; ninu ẹ̀jẹ ẹni pipa ati ti igbekun, lati ori awọn aṣaju ọtá.
43. Ẹ ma yọ̀, ẹnyin orilẹ-ède, pẹlu awọn enia rẹ̀: nitoripe on o gbẹsan ẹ̀jẹ awọn iranṣẹ rẹ̀, yio si gbẹsan lara awọn ọtá rẹ̀, yio si ṣètutu fun ilẹ rẹ̀, ati fun awọn enia rẹ̀.
44. Mose si wá o si sọ gbogbo ọ̀rọ ofin yi li etí awọn enia na, on, ati Hoṣea ọmọ Nuni.
45. Mose si pari sisọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo Israeli:
46. O si wi fun wọn pe, Ẹ gbé ọkàn nyin lé gbogbo ọ̀rọ ti mo sọ lãrin nyin li oni; ti ẹnyin o palaṣẹ fun awọn ọmọ nyin lati ma kiyesi ati ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi.
47. Nitoripe ki iṣe ohun asan fun nyin; nitoripe ìye nyin ni, ati nipa eyi li ẹnyin o mu ọjọ́ nyin pẹ ni ilẹ na, nibiti ẹnyin ngòke Jordani lọ lati gbà a.
48. OLUWA si sọ fun Mose li ọjọ́ na gan, wipe,
49. Gùn òke Abarimu yi lọ, si òke Nebo, ti mbẹ ni ilẹ Moabu, ti o kọjusi Jeriko; ki o si wò ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli ni iní.
50. Ki o si kú lori òke na, nibiti iwọ ngùn lọ, ki a si kó ọ jọ sọdọ awọn enia rẹ; bi Aaroni arakunrin rẹ ti kú li òke Horu, ti a si kó o jọ sọdọ awọn enia rẹ̀:
51. Nitoriti ẹnyin ṣẹ̀ si mi lãrin awọn ọmọ Israeli ni ibi omi Meriba-Kadeṣi, li aginjù Sini; nitoriti ẹnyin kò yà mi simimọ́ lãrin awọn ọmọ Israeli.
52. Ṣugbọn iwọ o ri ilẹ na niwaju rẹ; ṣugbọn iwọ ki yio lọ sibẹ̀, si ilẹ na ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli.