23. Emi o kó ohun buburu jọ lé wọn lori; emi o si lò ọfà mi tán si wọn lara:
24. Ebi yio mu wọn gbẹ, oru gbigbona li a o fi run wọn, ati iparun kikorò; emi o si rán ehín ẹranko si wọn, pẹlu oró ohun ti nrakò ninu erupẹ.
25. Idà li ode, ati ipàiya ninu iyẹwu, ni yio run ati ọmọkunrin ati wundia, ọmọ ẹnu-ọmu, ati ọkunrin arugbo elewu irun pẹlu.
26. Mo wipe, Emi o tu wọn ká patapata, emi o si mu iranti wọn dá kuro ninu awọn enia:
27. Bikoṣepe bi mo ti bẹ̀ru ibinu ọtá, ki awọn ọtá wọn ki o má ba ṣe alaimọ̀, ati ki nwọn ki o má ba wipe, Ọwọ́ wa leke ni, ki isi ṣe OLUWA li o ṣe gbogbo eyi.
28. Nitori orilẹ-ède ti kò ní ìmọ ni nwọn, bẹ̃ni kò sí òye ninu wọn.
29. Ibaṣepe nwọn gbọ́n, ki òye eyi ki o yé wọn, nwọn iba rò igbẹhin wọn!