Deu 30:10-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bi iwọ ba gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́, ti a kọ sinu iwé ofin yi; bi iwọ ba si fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, yipada si OLUWA Ọlọrun rẹ.

11. Nitori aṣẹ yi ti mo pa fun ọ li oni, kò ṣoro jù fun ọ, bẹ̃ni kò jìna rere si ọ.

12. Kò sí li ọrun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio gòke lọ si ọrun fun wa, ti yio si mú u wá fun wa, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e?

13. Bẹ̃ni kò sí ni ìha keji okun, ti iwọ iba fi wipe, Tani yio rekọja okun lọ fun wa, ti yio si mú u fun wa wá, ki awa ki o le gbọ́ ọ, ki a si le ṣe e?

14. Ṣugbọn ọ̀rọ na li o wà nitosi rẹ girigiri yi, li ẹnu rẹ, ati li àiya rẹ, ki iwọ ki o le ma ṣe e.

15. Wò o, emi fi ìye ati ire, ati ikú ati ibi, siwaju rẹ li oni;

16. Li eyiti mo palaṣẹ fun ọ li oni lati ma fẹ́ OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma rìn li ọ̀na rẹ̀, ati lati ma pa aṣẹ rẹ̀, ati ìlana rẹ̀, ati idajọ rẹ̀ mọ́, ki iwọ ki o le yè, ki o si ma bisi i, ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le busi i fun ọ ni ilẹ na, nibiti iwọ nlọ lati gbà a.

17. Ṣugbọn bi àiya rẹ ba pada, ti iwọ kò ba si gbọ́, ṣugbọn ti iwọ di ẹni fifà lọ, ti iwọ si mbọ oriṣa, ti iwọ si nsìn wọn;

Deu 30