Deu 29:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. OLUWA yio si yà a si ibi kuro ninu gbogbo ẹ̀ya Israeli, gẹgẹ bi gbogbo egún majẹmu, ti a kọ sinu iwé ofin yi.

22. Ati iran ti mbọ̀, awọn ọmọ nyin ti yio dide lẹhin nyin, ati alejò ti yio ti ilẹ jijìn wá, yio si wi, nigbati nwọn ba ri iyọnu ilẹ na, ati àrun na, ti OLUWA mu bá a;

23. Ati pe gbogbo ilẹ rẹ̀ di imi-õrùn, ati iyọ̀, ati ijóna, ti a kò le gbìn nkan si, tabi ti kò le seso, tabi ti koriko kò le hù ninu rẹ̀, bi ibìṣubu Sodomu, ati Gomorra, Adma, ati Seboiimu, ti OLUWA bìṣubu ninu ibinu rẹ̀, ati ninu ikannu rẹ̀:

24. Ani gbogbo orilẹ-ède yio ma wipe, Ẽṣe ti OLUWA fi ṣe bayi si ilẹ yi? Kili a le mọ̀ õru ibinu nla yi si?

25. Nwọn o si wipe, Nitoriti nwọn kọ̀ majẹmu OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o ti bá wọn dá nigbati o mú wọn lati ilẹ Egipti jade wá.

26. Nitoriti nwọn lọ, nwọn si bọ oriṣa, nwọn si tẹriba fun wọn, oriṣa ti nwọn kò mọ̀ rí, ti on kò si fi fun wọn.

Deu 29