Deu 29:1-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI li ọ̀rọ majẹmu ti OLUWA palaṣẹ fun Mose lati bá awọn ọmọ Israeli dá ni ilẹ Moabu, lẹhin majẹmu ti o ti bá wọn dá ni Horebu.

2. Mose si pè gbogbo awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti ri ohun gbogbo ti OLUWA ṣe li oju nyin ni ilẹ Egipti si Farao, ati si gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ ati si ilẹ rẹ̀ gbogbo.

3. Idanwò nla ti oju rẹ ti ri, iṣẹ-àmi, ati iṣẹ-iyanu nla wọnni:

4. Ṣugbọn OLUWA kò fun nyin li àiya lati mọ̀, ati oju lati ri, ati etí lati gbọ́ titi di oni yi.

5. Emi si ti mu nyin rìn li ogoji ọdún li aginjù: aṣọ nyin kò gbó mọ́ nyin li ara, bàta nyin kò si gbó mọ́ nyin ni ẹsẹ̀.

6. Ẹnyin kò jẹ àkara, bẹ̃li ẹnyin kò mu ọti-waini, tabi ọti lile: ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA Ọlọrun nyin.

7. Nigbati ẹnyin ti dé ihinyi, Sihoni ọba Hesboni, ati Ogu ọba Baṣani, jade ogun si wa, awa si kọlù wọn:

8. Awa si gbà ilẹ wọn, a si fi i fun awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse ni iní.

9. Nitorina, ẹ pa ọ̀rọ majẹmu yi mọ́, ki ẹ si ma ṣe wọn, ki ẹnyin ki o le ma ri ire ninu ohun gbogbo ti ẹnyin nṣe.

10. Gbogbo nyin li o duro li oni niwaju OLUWA Ọlọrun nyin; awọn olori nyin, awọn ẹ̀ya nyin, awọn àgba nyin, ati awọn ijoye nyin, ani gbogbo awọn ọkunrin Israeli,

11. Awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, awọn aya nyin, ati alejò rẹ, ti mbẹ lãrin ibudó rẹ, lati aṣẹgi rẹ dé apọnmi rẹ:

12. Ki iwọ ki o le wọ̀ inu majẹmu OLUWA Ọlọrun rẹ, ati ibura rẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ bá ọ ṣe li oni:

13. Ki o le fi idi rẹ kalẹ li oni li enia kan fun ara rẹ̀, ati ki on ki o le ma ṣe Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ fun ọ, ati bi o ti bura fun awọn baba rẹ, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu.

14. Ki si iṣe ẹnyin nikan ni mo bá ṣe majẹmu yi ati ibura yi;

15. Ṣugbọn ẹniti o bá wa duro nihin li oni niwaju OLUWA Ọlọrun wa, ẹniti kò sí nihin pẹlu wa li oni:

16. (Nitoripe ẹnyin mọ̀ bi awa ti gbé ilẹ Egipti; ati bi awa ti kọja lãrin orilẹ-ède ti ẹnyin là kọja;

17. Ẹnyin si ti ri ohun irira wọn, ati ere wọn, igi ati okuta, fadakà ati wurà, ti o wà lãrin wọn.)

18. Ki ẹnikẹni ki o má ba wà ninu nyin, ọkunrin, tabi obinrin, tabi idile, tabi ẹ̀ya, ti àiya rẹ̀ ṣí kuro lọdọ OLUWA Ọlọrun wa li oni, lati lọ isìn oriṣa awọn orilẹ-ède wọnyi; ki gbòngbo ti nyọ orõro ati iwọ, ki o má ba wà ninu nyin;

Deu 29