57. Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ.
58. Bi iwọ kò ba fẹ́ kiyesi ati ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi ti a kọ sinu iwé yi, lati ma bẹrù orukọ yi ti o lí ogo ti o si lí ẹ̀ru OLUWA ỌLỌRUN RẸ;
59. Njẹ OLUWA yio sọ iyọnu rẹ di iyanu, ati iyọnu irú-ọmọ rẹ, ani iyọnu nla, ati eyiti yio pẹ, ati àrun buburu, ati eyiti yio pẹ.
60. On o si mú gbogbo àrun Egipti pada wá bá ọ, ti iwọ bẹ̀ru; nwọn o si lẹ̀ mọ́ ọ.
61. Gbogbo àrun pẹlu, ati gbogbo iyọnu, ti a kò kọ sinu iwé ofin yi, awọn ni OLUWA yio múwa bá ọ, titi iwọ o fi run.
62. Diẹ li ẹnyin o si kù ni iye, ẹnyin ti ẹ ti dabi irawọ oju-ọrun ni ọ̀pọlọpọ: nitoriti iwọ kò gbà ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ gbọ́.
63. Yio si ṣe, bi OLUWA ti yọ̀ sori nyin lati ṣe nyin ni ire, ati lati sọ nyin di pupọ̀; bẹ̃ni OLUWA yio si yọ̀ si nyin lori lati run nyin, ati lati pa nyin run; a o si fà nyin tu kuro lori ilẹ na ni ibi ti iwọ nlọ lati gbà a.
64. OLUWA yio si tu ọ ká sinu enia gbogbo, lati opin ilẹ dé opin ilẹ; nibẹ̀ ni iwọ o si ma bọ oriṣa ti iwọ ati baba rẹ kò mọ̀ rí, ani igi ati okuta.
65. Ati lãrin orilẹ-ède wọnyi ni iwọ ki yio ri irọrun, bẹ̃li atẹlẹsẹ̀ rẹ ki yio ri isimi: ṣugbọn OLUWA yio fi iwarìri àiya, ati oju jijoro, ati ibinujẹ ọkàn fun ọ:
66. Ẹmi rẹ yio sọrọ̀ ni iyemeji li oju rẹ; iwọ o si ma bẹ̀ru li oru ati li ọsán, iwọ ki yio si ní idaniloju ẹmi rẹ.
67. Li owurọ̀ iwọ o wipe, Alẹ iba jẹ́ lẹ! ati li alẹ iwọ o wipe, Ilẹ iba jẹ́ mọ́! nitori ibẹ̀ru àiya rẹ ti iwọ o ma bẹ̀ru, ati nitori iran oju rẹ ti iwọ o ma ri.
68. OLUWA yio si fi ọkọ̀ tun mú ọ pada lọ si Egipti, li ọ̀na ti mo ti sọ fun ọ pe, Iwọ ki yio si tun ri i mọ́: nibẹ̀ li ẹnyin o si ma tà ara nyin fun awọn ọtá nyin li ẹrú ọkunrin ati ẹrú obinrin, ki yio si sí ẹniti yio rà nyin.