Deu 28:47-59 Yorùbá Bibeli (YCE)

47. Nitoriti iwọ kò fi àyọ sìn OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inudidun, nitori ọ̀pọ ohun gbogbo:

48. Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ.

49. OLUWA yio gbé orilẹ-ède kan dide si ọ lati ọ̀na jijìn, lati opin ilẹ wa bi idì ti ifò; orilẹ-ède ti iwọ ki yio gbọ́ ède rẹ̀;

50. Orilẹ-ède ọdaju, ti ki yio ṣe ojuṣaju arugbo, ti ki yio si ṣe ojurere fun ewe:

51. On o si ma jẹ irú ohunọ̀sin rẹ, ati eso ilẹ rẹ, titi iwọ o fi run: ti ki yio kù ọkà, ọti-waini, tabi oróro, tabi ibisi malu rẹ, tabi ọmọ agutan silẹ fun ọ, titi on o fi run ọ.

52. On o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, titi odi rẹ ti o ga ti o si le yio fi wó lulẹ, eyiti iwọ gbẹkẹle, ni ilẹ rẹ gbogbo: on o si dótì ọ ni ibode rẹ gbogbo, ni gbogbo ilẹ rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi fun ọ.

53. Iwọ o si jẹ ọmọ inu rẹ, ẹran ara awọn ọmọ rẹ ọkunrin ati ti awọn ọmọ rẹ obinrin ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ninu idótì na ati ninu ihámọ na ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́.

54. Ọkunrin ti àwọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, oju rẹ̀ yio korò si arakunrin rẹ̀, ati si aya õkanàiya rẹ̀, ati si iyokù ọmọ rẹ̀ ti on jẹ kù:

55. Tobẹ̃ ti on ki yio bùn ẹnikan ninu wọn, ninu ẹran awọn ọmọ ara rẹ̀ ti o jẹ, nitoriti kò sí ohun kan ti yio kù silẹ fun u ninu idótì na ati ninu ihámọ, ti awọn ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ gbogbo.

56. Obinrin ti awọ rẹ̀ tutù ninu nyin, ti o si ṣe ẹlẹgẹ, ti kò jẹ daṣa ati fi atẹlẹsẹ̀ rẹ̀ kan ilẹ nitori ikẹra ati ìwa-ẹlẹgẹ́, oju rẹ̀ yio korò si ọkọ õkanaiya rẹ̀, ati si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọ rẹ̀ obinrin;

57. Ati si ọmọ-ọwọ rẹ̀ ti o ti agbedemeji ẹsẹ̀ rẹ̀ jade, ati si awọn ọmọ rẹ̀ ti yio bi; nitoripe on o jẹ wọn ni ìkọkọ nitori ainí ohunkohun: ninu ìdótì ati ihámọ na, ti ọtá rẹ yio há ọ mọ́ ni ibode rẹ.

58. Bi iwọ kò ba fẹ́ kiyesi ati ma ṣe gbogbo ọ̀rọ ofin yi ti a kọ sinu iwé yi, lati ma bẹrù orukọ yi ti o lí ogo ti o si lí ẹ̀ru OLUWA ỌLỌRUN RẸ;

59. Njẹ OLUWA yio sọ iyọnu rẹ di iyanu, ati iyọnu irú-ọmọ rẹ, ani iyọnu nla, ati eyiti yio pẹ, ati àrun buburu, ati eyiti yio pẹ.

Deu 28