32. Awọn ọmọ rẹ ọkunrin, ati awọn ọmọ rẹ obinrin, li a o fi fun enia miran, oju rẹ yio ma wò, yio si su ọ lati ma wò ọ̀na wọn li ọjọ́ gbogbo: ki yio si sí agbara kan li ọwọ́ rẹ.
33. Eso ilẹ rẹ, ati gbogbo iṣẹ-lãlã rẹ, ni orilẹ-ède miran ti iwọ kò mọ̀ yio jẹ; iwọ o si jẹ́ kìki ẹni inilara ati ẹni itẹmọlẹ nigbagbogbo:
34. Bẹ̃ni iwọ o si di aṣiwere nitori iran oju rẹ, ti iwọ o ri.
35. OLUWA yio si fi õwo buburu lù ọ li ẽkún, ati li ẹsẹ̀, ti a ki o le wòsan, lati atẹlẹsẹ̀ rẹ dé atari rẹ.
36. OLUWA o mú iwọ, ati ọba rẹ ti iwọ o fi jẹ́ lori rẹ, lọ si orilẹ-ède ti iwọ, ati awọn baba rẹ kò mọ̀ rí; iwọ o si ma bọ oriṣa nibẹ̀, igi ati okuta.
37. Iwọ o si di ẹni iyanu, ati ẹni owe, ati ẹni ifisọrọsọ, ninu gbogbo orilẹ-ède, nibiti OLUWA yio gbé darí rẹ si.
38. Iwọ o mú irugbìn pupọ̀ lọ sinu oko, diẹ ni iwọ o si ri kójọ; nitoripe eṣú ni yio jẹ ẹ run.
39. Iwọ o gbìn ọgbà-àjara, iwọ o si ṣe itọju rẹ̀, ṣugbọn iwọ ki yio mu ninu ọti-waini rẹ̀, bẹ̃ni iwọ ki yio ká ninu eso-àjara rẹ̀, nitoripe kòkoro ni yio fi wọn jẹ.
40. Iwọ o ní igi olifi ni gbogbo àgbegbe rẹ, ṣugbọn iwọ ki yio fi oróro para; nitoripe igi olifi rẹ yio rẹ̀danu.
41. Iwọ o bi ọmọkunrin ati ọmọbinrin, ṣugbọn nwọn ki yio jẹ́ tirẹ; nitoripe nwọn o lọ si oko-ẹrú.
42. Gbogbo igi rẹ ati eso ilẹ rẹ yio jẹ́ ti eṣú.
43. Alejò ti mbẹ lãrin rẹ, yio ma ga jù ọ lọ siwaju ati siwaju, iwọ o si ma di ẹni irẹsilẹ, siwaju ati siwaju.
44. On ni yio ma wín ọ, iwọ ki yio si wín i: on ni yio ma ṣe ori, iwọ o si ma ṣe ìru.
45. Gbogbo egún wọnyi yio si wá sori rẹ, yio si lepa rẹ, yio si bá ọ, titi iwọ o fi run; nitoriti iwọ kò fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati pa aṣẹ rẹ̀ ati ìlana rẹ̀ mọ́ ti o palaṣe fun ọ.
46. Nwọn o si wà lori rẹ fun àmi ati fun iyanu, ati lori irú-ọmọ rẹ lailai:
47. Nitoriti iwọ kò fi àyọ sìn OLUWA Ọlọrun rẹ, ati inudidun, nitori ọ̀pọ ohun gbogbo:
48. Nitorina ni iwọ o ṣe ma sìn awọn ọtá rẹ ti OLUWA yio rán si ọ, ninu ebi, ati ninu ongbẹ, ati ninu ìhoho, ati ninu ainí ohun gbogbo: on o si fi àjaga irin bọ̀ ọ li ọrùn, titi yio fi run ọ.