1. YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ:
2. Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ.
3. Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko.
4. Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.
5. Ibukún ni fun agbọ̀n rẹ ati fun ọpọ́n-ipò-àkara rẹ.