1. YIO si ṣe, bi iwọ ba farabalẹ gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ, lati ma kiyesi ati ṣe aṣẹ rẹ̀ gbogbo ti mo pa fun ọ li oni, njẹ OLUWA Ọlọrun rẹ yio gbé ọ ga jù gbogbo orilẹ-ède aiye lọ:
2. Gbogbo ibukún wọnyi yio si ṣẹ sori rẹ, yio si bá ọ, bi iwọ ba fetisi ohùn OLUWA Ọlọrun rẹ.
3. Ibukún ni fun ọ ni ilu, ibukún ni fun ọ li oko.
4. Ibukún ni fun ọmọ inu rẹ, ati eso ilẹ rẹ, ati irú ohunọ̀sin rẹ, ati ibisi malu rẹ, ati ọmọ agutan rẹ.