Deu 26:16-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Li oni OLUWA Ọlọrun rẹ paṣẹ fun ọ lati ma ṣe ìlana ati idajọ wọnyi: nitorina ki iwọ ki o ma pa wọn mọ́, ki iwọ ki o si ma fi gbogbo àiya rẹ ati gbogbo ọkàn rẹ ṣe wọn.

17. Iwọ jẹwọ OLUWA li oni pe on ni Ọlọrun rẹ, ati pe iwọ o ma rìn li ọ̀na rẹ̀, iwọ o si ma pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, iwọ o si ma fetisi ohùn rẹ̀:

18. OLUWA si jẹwọ rẹ li oni pe iwọ o ma jẹ́ enia ọ̀tọ fun ara rẹ̀, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ati pe iwọ o ma pa gbogbo aṣẹ rẹ̀ mọ́;

19. On o si mu ọ ga jù orilẹ-ède gbogbo lọ ti o dá, ni ìyin, li orukọ, ati ọlá; ki iwọ ki o le ma jẹ́ enia mimọ́ fun OLUWA Ọlọrun rẹ, bi o ti sọ.

Deu 26