Iwọ jẹwọ OLUWA li oni pe on ni Ọlọrun rẹ, ati pe iwọ o ma rìn li ọ̀na rẹ̀, iwọ o si ma pa ìlana rẹ̀ mọ́, ati aṣẹ rẹ̀, ati idajọ rẹ̀, iwọ o si ma fetisi ohùn rẹ̀: