1. YIO si ṣe, nigbati iwọ ba dé ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní, ti iwọ si gbà a, ti iwọ si joko ninu rẹ̀;
2. Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.
3. Ki iwọ ki o si tọ̀ alufa na lọ ti yio wà li ọjọ́ wọnni, ki o si wi fun u pe, Emi jẹwọ li oni fun OLUWA Ọlọrun rẹ, pe emi wá si ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba wa lati fi fun wa.
4. Ki awọn alufa ki o si gbà agbọ̀n na li ọwọ́ rẹ, ki o si gbé e kalẹ niwaju pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ.
5. Iwọ o si dahùn iwọ o si wi niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ pe, Ara Siria kan, ti o nṣegbé ni baba mi, on si sọkalẹ lọ si Egipti, o si ṣe atipo nibẹ̀, ti on ti enia diẹ; nibẹ̀ li o si di orilẹ-ède nla, alagbara, ati pupọ̀:
6. Awọn ara Egipti si hùwabuburu si wa, nwọn si pọn wa loju, nwọn si dì ẹrù wuwo rù wa:
7. Awa si kepè OLUWA, Ọlọrun awọn baba wa, OLUWA si gbọ́ ohùn wa, o si wò ipọnju wa, ati lãlã wa, ati inira wa: