Ki iwọ ki o mú ninu akọ́so gbogbo eso ilẹ rẹ, ti iwọ o mú ti inu ile rẹ wá, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ; ki iwọ ki o si fi i sinu agbọ̀n, ki iwọ ki o si lọ si ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si.