1. BI a ba ri ẹnikan ti a pa ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ lati gbà a, ti o dubulẹ ni igbẹ́, ti a kò si mọ̀ ẹniti o pa a:
2. Nigbana ni ki awọn àgba rẹ ati awọn onidajọ rẹ ki o jade wá, ki nwọn ki o si wọ̀n jijìna awọn ilu ti o yi ẹniti a pa na ká.
3. Yio si ṣe, pe ilu ti o sunmọ ẹniti a pa na, ani awọn àgba ilu na ki nwọn mú ẹgbọrọ abo-malu kan, ti a kò fi ṣiṣẹ rí, ti kò si fà ninu àjaga rí;
4. Ki awọn àgba ilu na ki o mú ẹgbọrọ abo-malu na sọkalẹ wá, si afonifoji ti o ní omi ṣiṣàn kan, ti a kò ro ti a kò si gbìn, ki nwọn ki o si ṣẹ́ ọrùn ẹgbọrọ abomalu na nibẹ̀ li afonifoji na:
5. Awọn alufa, awọn ọmọ Lefi yio si sunmọtosi; nitoripe awọn ni OLUWA Ọlọrun rẹ yàn lati ma ṣe iṣẹ-ìsin fun u, ati lati ma sure li orukọ OLUWA; nipa ọ̀rọ wọn li a o ti ma wadi ọ̀ran iyàn ati ọ̀ran lilù:
6. Ati gbogbo awọn àgba ilu nì, ti o sunmọ ẹniti a pa na, ki nwọn ki o wẹ̀ ọwọ́ wọn sori ẹgbọrọ abo-malu na, ti a ṣẹ́ li ọrùn li afonifoji nì:
7. Ki nwọn ki o si dahùn wipe, Ọwọ́ wa kò tà ẹ̀jẹ yi silẹ, bẹ̃li oju wa kò ri i.
8. OLUWA, darijì Israeli awọn enia rẹ, ti iwọ ti ràpada, ki o má si ṣe kà ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ si ọrùn Israeli awọn enia rẹ. A o si dari ẹ̀jẹ na jì wọn.
9. Bẹ̃ni iwọ o si mú ẹ̀jẹ alaiṣẹ̀ kuro lãrin nyin, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.
10. Nigbati iwọ ba jade ogun si awọn ọtá rẹ, ti OLUWA Ọlọrun rẹ si fi wọn lé ọ lọwọ, ti iwọ si dì wọn ni igbekun;
11. Ti iwọ ba si ri ninu awọn igbẹsin na arẹwà obinrin, ti iwọ si ní ifẹ́ si i, pe ki iwọ ki o ní i li aya rẹ;
12. Nigbana ni ki iwọ ki o mú u wá sinu ile rẹ; ki on ki o si fá ori rẹ̀, ki o si rẹ́ ẽkanna rẹ̀;