14. Ìgba ti awa fi ti Kadeṣi-barnea wá, titi awa fi gòke odò Seredi lọ, o jẹ́ ọgbọ̀n ọdún o le mẹjọ; titi gbogbo iran awọn ologun fi run kuro ninu ibudó, bi OLUWA ti bura fun wọn.
15. Pẹlupẹlu ọwọ́ OLUWA lodi si wọn nitõtọ, lati run wọn kuro ninu ibudó, titi nwọn fi run tán.
16. Bẹ̃li o si ṣe, ti gbogbo awọn ologun nì run, ti nwọn si kú tán ninu awọn enia na,
17. OLUWA si sọ fun mi pe,
18. Iwọ o là ilẹ Ari lọ li oni, li àgbegbe Moabu:
19. Nigbati iwọ ba sunmọtosi awọn ọmọ Ammoni, máṣe bi wọn ninu, bẹ̃ni ki o máṣe bá wọn jà: nitoripe emi ki yio fi ninu ilẹ awọn ọmọ Ammoni fun ọ ni iní: nitoriti mo ti fi i fun awọn ọmọ Lotu ni iní.
20. (A si kà eyinì pẹlu si ilẹ awọn omirán; awọn omirán ti ngbé inu rẹ̀ rí; awọn ọmọ Ammoni a si ma pè wọn ni Samsummimu.
21. Awọn enia nla, ti nwọn si pọ̀, nwọn si sigbọnlẹ, bi awọn ọmọ Anaki; ṣugbọn OLUWA run wọn niwaju wọn; nwọn si tẹle wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn;
22. Bi o ti ṣe fun awọn ọmọ Esau, ti ngbé Seiri, nigbati o run awọn ọmọ Hori kuro niwaju wọn; ti nwọn si tẹle wọn, ti nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn titi di oni-oloni: