Deu 14:15-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ati ogongo, ati owiwi, ati ẹlulu, ati awodi li onirũru rẹ̀;

16. Owiwi kekere, ati owiwi nla, ati ogbugbu;

17. Ati pelikan, ati àkala, ati ìgo;

18. Ati àkọ, ati ondẹ li onirũru rẹ̀, ati atọka, ati adán.

19. Ati ohun gbogbo ti nrakò ti nfò, o jẹ́ alaimọ́ fun nyin: a kò gbọdọ jẹ wọn.

20. Ṣugbọn gbogbo ẹiyẹ ti o mọ́ ni ki ẹnyin ki o ma jẹ.

21. Ẹnyin kò gbọdọ jẹ ohunkohun ti o tikara rẹ̀ kú: iwọ le fi i fun alejò ti mbẹ ninu ibode rẹ, ki on ki o jẹ ẹ; tabi ki iwọ ki o tà a fun ajeji: nitoripe enia mimọ́ ni iwọ fun OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.

22. Ki iwọ ki o dá idamẹwa gbogbo ibisi irugbìn rẹ, ti nti oko rẹ wá li ọdọdún.

23. Niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ni ibi ti on o gbé yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, ni ki iwọ ki o si ma jẹ idamẹwa ọkà rẹ, ti ọti-waini rẹ, ati ti oróro rẹ, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran rẹ, ati ti agbo-ẹran rẹ; ki iwọ ki o le ma kọ́ ati bẹ̀ru OLUWA Ọlọrun rẹ nigbagbogbo.

24. Bi ọ̀na na ba si jìn jù fun ọ, ti iwọ ki yio fi le rù u lọ, tabi bi ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si ba jìn jù fun ọ, nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba bukún ọ:

25. Njẹ ki iwọ ki o yi i si owo, ki iwọ ki o si dì owo na li ọwọ́ rẹ, ki o si lọ si ibi na, ti OLUWA Ọlọrun rẹ yio yàn.

26. Ki iwọ ki o si ná owo na si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́, si akọmalu, tabi agutan, tabi ọti-waini, tabi ọti lile kan, tabi si ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́: ki iwọ ki o si ma jẹ nibẹ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma yọ̀, iwọ, ati awọn ara ile rẹ:

27. Ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode rẹ; iwọ kò gbọdọ kọ̀ ọ silẹ; nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ.

28. Li opin ọdún mẹta ni ki iwọ ki o mú gbogbo idamẹwa ibisi rẹ wa li ọdún na, ki iwọ ki o si gbé e kalẹ ninu ibode rẹ:

29. Ati ọmọ Lefi, nitoriti kò ní ipín tabi iní pẹlu rẹ, ati alejò, ati alainibaba, ati opó, ti mbẹ ninu ibode rẹ, yio wá, nwọn o si jẹ nwọn o si yó; ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le bukún ọ ninu gbogbo iṣẹ ọwọ́ rẹ ti iwọ nṣe.

Deu 14