Deu 12:19-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ ki o máṣe kọ̀ ọmọ Lefi silẹ ni gbogbo ọjọ́ rẹ lori ilẹ.

20. Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba sọ àgbegbe rẹ di nla, bi on ti ṣe ileri fun ọ, ti iwọ ba si wipe, Emi o jẹ ẹran, nitoriti ọkàn rẹ nfẹ́ ẹran ijẹ; ki iwọ ki o ma jẹ ẹran, ohunkohun ti ọkàn rẹ ba nfẹ́.

21. Bi o ba ṣepe, ibi ti OLUWA Ọlọrun rẹ ba yàn, lati fi orukọ rẹ̀ si, ba jìna jù fun ọ, njẹ ki iwọ ki o pa ninu ọwọ́-ẹran rẹ ati ninu agbo-ẹran rẹ, ti OLUWA fi fun ọ, bi emi ti fi aṣẹ fun o, ki iwọ ki o si ma jẹ ohunkohun ti ọkàn rẹ ba fẹ́ ninu ibode rẹ.

22. Ani bi ã ti ijẹ esuro, ati agbọnrin, bẹ̃ni ki iwọ ki o ma jẹ wọn: alaimọ́ ati ẹni mimọ́ yio jẹ ninu wọn bakanna.

23. Kìki ki o ṣọ́ ara rẹ gidigidi ki iwọ ki o máṣe jẹ ẹ̀jẹ: nitoripe ẹ̀jẹ li ẹmi; iwọ kò si gbọdọ jẹ ẹmi pẹlu ẹran.

24. Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; iwọ o dà a silẹ bi omi.

25. Iwọ kò gbọdọ jẹ ẹ; ki o le ma dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ, nigbati iwọ ba nṣe eyiti o tọ́ li oju OLUWA.

26. Kìki ohun mimọ́ rẹ ti iwọ ní, ati ẹjẹ́ rẹ ni ki iwọ ki o mú, ki o si lọ si ibi ti OLUWA yio yàn:

27. Ki iwọ ki o si ma ru ẹbọ sisun rẹ, ẹran ati ẹ̀jẹ na, lori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ: ati ẹ̀jẹ ẹbọ rẹ ni ki a dà sori pẹpẹ OLUWA Ọlọrun rẹ, ki iwọ ki o si ma jẹ ẹran na.

28. Kiyesara ki o si ma gbọ́ gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti mo palaṣẹ fun ọ, ki o le dara fun ọ, ati fun awọn ọmọ rẹ lẹhin rẹ lailai, nigbati iwọ ba ṣe eyiti o dara ti o si tọ́ li oju OLUWA Ọlọrun rẹ.

29. Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba ke awọn orilẹ-ède wọnni kuro niwaju rẹ, nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà wọn, ti iwọ si rọpò wọn, ti iwọ si joko ni ilẹ wọn;

30. Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ má ba bọ́ si idẹkùn ati tẹle wọn lẹhin, lẹhin igbati a ti run wọn kuro niwaju rẹ; ki iwọ ki o má si bère oriṣa wọn, wipe, Bawo li awọn orilẹ-ède wọnyi ti nsìn oriṣa wọn? emi o si ṣe bẹ̃ pẹlu.

31. Iwọ kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun rẹ; nitoripe gbogbo ohun irira si OLUWA, ti on korira ni nwọn ti nṣe si awọn oriṣa wọn; nitoripe awọn ọmọkunrin, ati awọn ọmọbinrin wọn pẹlu ni nwọn nsun ninu iná fun oriṣa wọn.

32. Ohunkohun ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin, ẹ ma kiyesi lati ṣe e: iwọ kò gbọdọ fikún u, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ bù kuro ninu rẹ̀.

Deu 12