Ma ṣọ́ ara rẹ ki iwọ má ba bọ́ si idẹkùn ati tẹle wọn lẹhin, lẹhin igbati a ti run wọn kuro niwaju rẹ; ki iwọ ki o má si bère oriṣa wọn, wipe, Bawo li awọn orilẹ-ède wọnyi ti nsìn oriṣa wọn? emi o si ṣe bẹ̃ pẹlu.