Deu 12:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. WỌNYI ni ìlana ati idajọ, ti ẹnyin o ma kiyesi lati ma ṣe ni ilẹ na ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ fi fun ọ lati ní, ni gbogbo ọjọ́ ti ẹnyin o wà lori ilẹ-aiye.

2. Ki ẹnyin ki o run ibi gbogbo wọnni patapata, nibiti awọn orilẹ-ède nì, ti ẹnyin o gbà, nsìn oriṣa wọn, lori òke giga, ati lori òke kekeké, ati labẹ igi tutù gbogbo:

3. Ki ẹnyin ki o si wó pẹpẹ wọn, ki ẹ si bì ọwọ̀n wọn ṣubu, ki ẹ si fi iná kun igbo oriṣa wọn; ki ẹnyin ki o si ke ere fifin wọn lulẹ, ki ẹ si run orukọ wọn kuro ni ibẹ na.

4. Ẹnyin kò gbọdọ ṣe bẹ̃ si OLUWA Ọlọrun nyin.

5. Ṣugbọn ibi ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn ninu gbogbo ẹ̀ya nyin lati fi orukọ rẹ̀ si, ani ibujoko rẹ̀ li ẹnyin o ma wálọ, ati nibẹ̀ ni ki iwọ ki o ma wá:

6. Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o ma mú ẹbọ sisun nyin wá, ati ẹbọ nyin, ati idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati ẹjẹ́ nyin, ati ẹbọ ifẹ́-atinuwa nyin, ati akọ́bi ọwọ́-ẹran nyin ati ti agbo-ẹran nyin:

7. Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ma jẹ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ ninu ohun gbogbo ti ẹnyin fi ọwọ́ nyin lé, ẹnyin ati awọn ara ile nyin, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún u fun ọ.

8. Ki ẹnyin ki o máṣe ṣe gẹgẹ bi gbogbo ohun ti awa nṣe nihin li oni, olukuluku enia ohun ti o tọ́ li oju ara rẹ̀:

9. Nitoripe ẹnyin kò sá ti idé ibi-isimi, ati ilẹ iní, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin.

10. Ṣugbọn nigbati ẹnyin ba gòke Jordani, ti ẹnyin si joko ni ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin ni iní, ti o ba si fun nyin ni isimi kuro lọwọ awọn ọtá nyin gbogbo yiká, ti ẹnyin si joko li alafia:

11. Nigbana ni ibikan yio wà ti OLUWA Ọlọrun nyin yio yàn lati fi orukọ rẹ̀ si, nibẹ̀ li ẹnyin o ma mú gbogbo ohun ti mo palaṣẹ fun nyin wá; ẹbọ sisun nyin, ati ẹbọ nyin, idamẹwa nyin, ati ẹbọ igbesọsoke ọwọ́ nyin, ati gbogbo àṣayan ẹjẹ́ nyin ti ẹnyin jẹ́ fun OLUWA.

12. Ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ẹnyin, ati awọn ọmọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ nyin obinrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin ọkunrin, ati awọn ọmọ-ọdọ nyin obinrin, ati ọmọ Lefi ti mbẹ ninu ibode nyin, nitori on kò ní ipín tabi iní pẹlu nyin.

Deu 12