Nibẹ̀ ni ki ẹnyin ki o si ma jẹ niwaju OLUWA Ọlọrun nyin, ki ẹnyin ki o si ma yọ̀ ninu ohun gbogbo ti ẹnyin fi ọwọ́ nyin lé, ẹnyin ati awọn ara ile nyin, ninu eyiti OLUWA Ọlọrun rẹ fi bukún u fun ọ.