29. Nigbana ni mo wi fun nyin pe, Ẹ máṣe fòya, bẹ̃ni ki ẹ máṣe bẹ̀ru wọn.
30. OLUWA Ọlọrun nyin ti nṣaju nyin, on ni yio jà fun nyin, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe fun nyin ni Egipti li oju nyin;
31. Ati li aginjù, nibiti iwọ ri bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti gbé ọ, bi ọkunrin ti igbé ọmọ rẹ̀, li ọ̀na nyin gbogbo ti ẹnyin rìn, titi ẹnyin fi dé ihinyi.
32. Sibẹ̀ ninu nkan yi ẹnyin kò gbà OLUWA Ọlọrun nyin gbọ́.
33. Ti nlọ li ọ̀na ṣaju nyin, lati wá ibi fun nyin, ti ẹnyin o pagọ́ nyin si, ninu iná li oru, lati fi ọ̀na ti ẹnyin o gbà hàn nyin, ati ninu awọsanma li ọsán.
34. OLUWA si gbọ́ ohùn ọ̀rọ nyin, o si binu, o si bura, wipe,
35. Nitõtọ ọkan ninu awọn ọkunrin wọnyi ti iran buburu yi, ki yio ri ilẹ rere na, ti mo ti bura lati fi fun awọn baba nyin,
36. Bikoṣe Kalebu ọmọ Jefunne, on ni yio ri i; on li emi o fi ilẹ na ti o tẹ̀mọlẹ fun, ati fun awọn ọmọ rẹ̀: nitoriti o tẹle OLUWA lẹhin patapata.
37. OLUWA si binu si mi pẹlu nitori nyin, wipe, Iwọ pẹlu ki yio dé ibẹ̀:
38. Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i.
39. Ati awọn ọmọ wẹ́wẹ nyin, ti ẹnyin wipe nwọn o di ijẹ, ati awọn ọmọ nyin, ti nwọn kò mọ̀ rere tabi buburu loni yi, awọn ni o dé ibẹ̀, awọn li emi o si fi i fun, awọn ni yio si ní i.
40. Ṣugbọn bi o ṣe ti nyin ni, ẹ pada, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n lọ si aginjù li ọ̀na Okun Pupa.
41. Nigbana li ẹ dahùn, ẹ si wi fun mi pe, Awa ti ṣẹ̀ si OLUWA, awa o gòke lọ, a o si jà, gẹgẹ bi gbogbo eyiti OLUWA Ọlọrun wa palaṣẹ fun wa. Ati olukuluku nyin dì ihamọra ogun rẹ̀, ẹnyin mura lati gùn ori òke na.
42. OLUWA si wi fun mi pe, Wi fun wọn pe, Ẹ máṣe gòke lọ, bẹ̃ni ki ẹ màṣe jà; nitoriti emi kò sí lãrin nyin; ki a má ba lé nyin niwaju awọn ọtá nyin.
43. Mo sọ fun nyin, ẹnyin kò si gbọ́; ẹnyin ṣọ̀tẹ si aṣẹ OLUWA, ẹnyin sì kùgbu lọ si ori òke na.
44. Awọn ọmọ Amori, ti ngbé ori òke na, si jade tọ̀ nyin wá, nwọn si lepa nyin, bi oyin ti iṣe, nwọn si run nyin ni Seiri, titi dé Horma.
45. Ẹnyin si pada ẹ sì sọkun niwaju OLUWA; ṣugbọn OLUWA kò gbọ́ ohùn nyin, bẹ̃ni kò fetisi nyin.
46. Ẹnyin si joko ni Kadeṣi li ọjọ́ pupọ̀, gẹgẹ bi ọjọ́ ti ẹnyin joko nibẹ̀.