Dan 6:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba;

2. Ati lori awọn wọnyi ni alakoso mẹta: Danieli si jẹ ọkan ninu wọn: ki awọn arẹ bãlẹ ki o le ma jiyin fun wọn, ki ọba ki o má ṣe ni ipalara.

3. Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba.

4. Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀.

5. Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀.

Dan 6