5. Pe, akokò ki akokò ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki ẹnyin wolẹ, ki ẹ si tẹriba fun ere wura ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.
6. Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.
7. Nitorina, lakokò na nigbati gbogbo enia gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, ati oniruru orin gbogbo, gbogbo enia, orilẹ, ati ède wolẹ, nwọn si tẹriba fun ere wura na ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.
8. Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn.
9. Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́.
10. Iwọ ọba ti paṣẹ pe, bi ẹnikẹni ba ti gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki o wolẹ ki o si tẹriba fun ere wura na.
11. Ẹnikẹni ti kò ba si wolẹ ki o tẹriba, ki a gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.
12. Awọn ara Juda kan wà, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego ti iwọ fi ṣe olori ọ̀ran igberiko Babeli: Ọba, awọn ọkunrin wọnyi kò kà ọ si, nwọn kò sìn oriṣa rẹ, nwọn kò si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.