3. Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ.
4. Nigbana ni akede kigbe soke pe, A pa a laṣẹ fun nyin, ẹnyin enia, orilẹ, ati ède gbogbo,
5. Pe, akokò ki akokò ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki ẹnyin wolẹ, ki ẹ si tẹriba fun ere wura ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.
6. Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.
7. Nitorina, lakokò na nigbati gbogbo enia gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, ati oniruru orin gbogbo, gbogbo enia, orilẹ, ati ède wolẹ, nwọn si tẹriba fun ere wura na ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.
8. Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn.
9. Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́.