Dan 3:3-17 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Nigbana li awọn ọmọ-alade, awọn bãlẹ, ati awọn balogun, awọn onidajọ, awọn oluṣọ iṣura, awọn ìgbimọ, awọn ijoye, ati gbogbo awọn olori igberiko pejọ si iyasi-mimọ́ ere ti Nebukadnessari gbe kalẹ, nwọn si duro niwaju ere ti Nebukadnessari gbé kalẹ.

4. Nigbana ni akede kigbe soke pe, A pa a laṣẹ fun nyin, ẹnyin enia, orilẹ, ati ède gbogbo,

5. Pe, akokò ki akokò ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki ẹnyin wolẹ, ki ẹ si tẹriba fun ere wura ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.

6. Ẹniti kò ba si wolẹ̀, ki o si tẹriba, lojukanna li a o gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.

7. Nitorina, lakokò na nigbati gbogbo enia gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, ati oniruru orin gbogbo, gbogbo enia, orilẹ, ati ède wolẹ, nwọn si tẹriba fun ere wura na ti Nebukadnessari ọba gbé kalẹ.

8. Lakokò na ni awọn ọkunrin ara Kaldea kan wá, nwọn si fi awọn ara Juda sùn.

9. Nwọn dahùn, nwọn si wi fun Nebukadnessari ọba, pe, Ki ọba ki o pẹ́.

10. Iwọ ọba ti paṣẹ pe, bi ẹnikẹni ba ti gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ki o wolẹ ki o si tẹriba fun ere wura na.

11. Ẹnikẹni ti kò ba si wolẹ ki o tẹriba, ki a gbé e sọ si ãrin iná ileru ti njo.

12. Awọn ara Juda kan wà, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego ti iwọ fi ṣe olori ọ̀ran igberiko Babeli: Ọba, awọn ọkunrin wọnyi kò kà ọ si, nwọn kò sìn oriṣa rẹ, nwọn kò si tẹriba fun ere wura ti iwọ gbé kalẹ.

13. Nigbana ni Nebukadnessari ọba paṣẹ ni ibinu ati irunu rẹ̀, pe, ki nwọn ki o mu Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego wá. Nigbana ni a si mu awọn ọkunrin wọnyi wá siwaju ọba.

14. Nebukadnessari dahùn, o si wi fun wọn pe, otitọ ha ni, Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego, pe, ẹnyin kò sìn oriṣa mi, ẹ kò si tẹriba fun ere wura na ti mo gbé kalẹ?

15. Njẹ bi ẹnyin ba mura pe, li akokò ti o wù ki o ṣe ti ẹnyin ba gbọ́ ohùn ipè, fère, duru, ìlu, orin, katè, ati oniruru orin, ti ẹ ba wolẹ ti ẹ ba si tẹriba fun ere wura ti mo yá, yio ṣe gẹgẹ; ṣugbọn bi ẹnyin kò ba tẹriba, a o gbé nyin ni wakati kanna sọ si ãrin iná ileru ti njo; ta li Ọlọrun na ti yio si gbà nyin kuro li ọwọ mi.

16. Ṣadraki, Meṣaki, ati Abednego dahùn, nwọn si wi fun ọba pe, Nebukadnessari, kò tọ si wa lati fi èsi kan fun ọ nitori ọ̀ran yi.

17. Bi o ba ri bẹ̃, Ọlọrun wa ti awa nsìn, le gbà wa lọwọ iná ileru na ti njo, on o si gbà wa lọwọ rẹ, ọba.

Dan 3