Nigbana li ọba sọ Danieli di ẹni-nla, o si fun u li ẹ̀bun nla pupọ, o si fi i jẹ olori gbogbo igberiko Babeli, ati olori onitọju gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli.