Amo 2:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BAYI li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Moabu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o ti sun egungun ọba Edomu di ẽrú.

2. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Moabu, yio si jó ãfin Kirioti wọnni run: Moabu yio si kú pẹlu ariwo, pẹlu iho ayọ̀, ati pẹlu iro ipè:

3. Emi o si ké onidajọ kurò lãrin rẹ̀, emi o si pa gbogbo ọmọ-alade inu rẹ̀ pẹlu rẹ̀; li Oluwa wi.

4. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Juda, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti gàn ofin Oluwa, nwọn kò si pa aṣẹ rẹ̀ mọ, eke wọn si ti mu wọn ṣina, eyiti awọn baba wọn ti tẹ̀le.

5. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara Juda, yio si jó ãfin Jerusalemu wọnni run.

6. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji;

7. Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ.

Amo 2