4. Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run.
5. Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi.
6. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti kó gbogbo igbèkun ni igbèkun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ.
7. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run:
8. Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi.
9. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Tire, ati nitori mẹrin: emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn fi gbogbo igbèkun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin.
10. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run.