25. Awọn ọkunrin Ṣekemu si yàn awọn enia ti o ba dè e lori òke, gbogbo awọn ti nkọja lọdọ wọn ni nwọn si njà a li ole: nwọn si sọ fun Abimeleki.
26. Gaali ọmọ Ebedi si wá ti on ti awọn arakunrin rẹ̀, nwọn si kọja lọ si Ṣekemu: awọn ọkunrin Ṣekemu si gbẹkẹ wọn le e.
27. Nwọn si jade lọ si oko, nwọn si ká eso-àjara wọn, nwọn si fọ́n eso na, nwọn si nṣe ariya, nwọn si lọ si ile oriṣa wọn, nwọn si jẹ, nwọn si mu, nwọn si fi Abimeleki ré.
28. Gaali ọmọ Ebedi si wipe, Tani Abimeleki? ta si ni Ṣekemu, ti awa o fi ma sìn i? Ṣe ọmọ Jerubbaali ni iṣe? ati Sebulu ijoye rẹ̀? ẹ mã sìn awọn ọkunrin Hamoru baba Ṣekemu: ṣugbọn nitori kili awa o ha ṣe ma sìn on?
29. Awọn enia wọnyi iba wà ni ikawọ mi! nigbana ni emi iba ṣí Abimeleki ni ipò. On si wi fun Abimeleki pe, Gbá ogun kún ogun rẹ, ki o si jade.
30. Nigbati Sebulu alaṣẹ ilu na si gbọ́ ọ̀rọ Gaali ọmọ Ebedi, o binu gidigidi.
31. On si rán awọn onṣẹ ìkọkọ si Abimeleki, wipe, Kiyesi i, Gaali ọmọ Ebedi ati awọn arakunrin rẹ̀ wá si Ṣekemu; si kiyesi i, nwọn rú ilú na sokè si ọ.
32. Njẹ nitorina, dide li oru, iwọ ati awọn enia ti o wà pẹlu rẹ, ki ẹnyin ki o si ba sinu oko:
33. Yio si ṣe, li owurọ̀, lojukanna bi õrùn ba si ti là, ki iwọ ki o dide ni kùtukutu owurọ̀, ki iwọ ki o si kọlù ilu na: si kiyesi i, nigbati on ati awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀ ba jade tọ̀ ọ, nigbana ni ki iwọ ki o ṣe si wọn bi iwọ ba ti ri pe o yẹ.
34. Abimeleki si dide, ati gbogbo awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀ li oru, nwọn si ba ni ipa mẹrin leti Ṣekemu.
35. Gaali ọmọ Ebedi si jade, o si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na: Abimeleki si dide, ati awọn enia ti o wà lọdọ rẹ̀, kuro ni ibùba.