A. Oni 9:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ABIMELEKI ọmọ Jerubbaali si lọ si Ṣekemu sọdọ awọn arakunrin iya rẹ̀, o si bá wọn sọ̀rọ, ati gbogbo idile ile baba iya rẹ̀, wipe,

2. Emi bẹ̀ nyin, ẹ sọ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu pe, Ẽwo li o rọ̀run fun nyin, ki gbogbo awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, ki o ṣe olori nyin, tabi ki ẹnikan ki o ṣe olori nyin? ki ẹnyin ki o ranti pẹlu pe, emi li egungun nyin, ati ẹran ara nyin.

3. Awọn arakunrin iya rẹ̀ si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi nitori rẹ̀ li etí gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu: àiya wọn si tẹ̀ si ti Abimeleki; nitori nwọn wipe, Arakunrin wa ni iṣe.

4. Nwọn si fun u li ãdọrin owo fadakà lati inu ile Baali-beriti wá, Abimeleki si fi i bẹ̀ awọn enia lasan ati alainilari li ọ̀wẹ, nwọn si ntẹ̀le e.

5. On si lọ si ile baba rẹ̀ ni Ofra, o si pa awọn arakunrin rẹ̀ awọn ọmọ Jerubbaali, ãdọrin enia, lori okuta kan: ṣugbọn o kù Jotamu abikẹhin ọmọ Jerubbaali; nitoriti o sapamọ́.

6. Gbogbo awọn ọkunrin Ṣekemu si kó ara wọn jọ, ati gbogbo awọn ara ile Millo, nwọn lọ nwọn si fi Abimeleki jẹ́ ọba, ni ibi igi-oaku ile-ẹṣọ́ ti mbẹ ni Ṣekemu.

7. Nigbati nwọn si sọ fun Jotamu, on si lọ o si duro lori òke Gerisimu, o si gbé ohùn rẹ̀ soke, o kigbe, o si wi fun wọn pe, Ẹ fetisi ti emi, ẹnyin ọkunrin Ṣekemu, ki Ọlọrun ki o le fetisi ti nyin.

8. Awọn igi lọ li akokò kan ki nwọn ki o le fi ọba jẹ́ lori wọn; nwọn si wi fun igi olifi pe, Wá jọba lori wa.

9. Ṣugbọn igi olifi wi fun wọn pe, Emi ha le fi ọrá mi silẹ, nipa eyiti nwọn nfi mi bù ọlá fun Ọlọrun ati enia, ki emi ki o si wá ṣe olori igi?

A. Oni 9