10. Ẹ sọ ọ, ẹnyin ti ngùn kẹtẹkẹtẹ funfun, ẹnyin ti njoko lori ẹni daradara, ati ẹnyin ti nrìn li ọ̀na.
11. Li ọ̀na jijìn si ariwo awọn tafàtafa nibiti a gbé nfà omi, nibẹ̀ ni nwọn o gbé sọ iṣẹ ododo OLUWA, ani iṣẹ ododo ijọba rẹ̀ ni Israeli. Nigbana ni awọn enia OLUWA sọkalẹ lọ si ibode.
12. Jí, jí, Debora; Jí, jí, kọ orin: dide, Baraki, ki o si ma kó awọn igbekun rẹ ni igbekun, iwọ ọmọ Abinoamu.
13. Nigbana ni iyokù ninu awọn ọlọ̀tọ ati awọn enia sọkalẹ; OLUWA sọkalẹ sori awọn alagbara fun mi.
14. Lati Efraimu ni nwọn ti wá awọn ti gbongbo wọn wà ni Amaleki; lẹhin rẹ, Benjamini, lãrin awọn enia rẹ; lati Makiri ni awọn alaṣẹ ti sọkalẹ wá, ati lati Sebuluni li awọn ẹniti nmú ọ̀pá-oyè lọwọ.
15. Awọn ọmọ-alade Issakari wà pẹlu Debora; bi Issakari ti ri, bẹ̃ni Baraki; nwọn sure li ẹsẹ̀ lọ si afonifoji na. Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
16. Ẽṣe ti iwọ fi joko lãrin agbo-agutan lati ma gbọ́ fere oluṣọ-agutan? Ni ipadò Reubeni ni ìgbero pupọ̀ wà.
17. Gileadi joko loke odò Jordani: ẽṣe ti Dani fi joko ninu ọkọ̀? Aṣeri joko leti okun, o si ngbé ebute rẹ̀.
18. Sebuluni li awọn enia, ti o fi ẹmi wọn wewu ikú, ati Naftali, ni ibi giga pápa.