A. Oni 20:42-46 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Nitorina, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọkunrin Israeli si ọ̀na ijù; ṣugbọn ogun na lepa wọn kikan; ati awọn ti o ti ilu wọnni jade wá ni nwọn pa lãrin wọn.

43. Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn.

44. Ẹgba mẹsan ọkunrin li o si ṣubu ninu awọn enia Benjamini, gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.

45. Nwọn si yipada nwọn sálọ si ìha ijù sori okuta Rimmoni: nwọn si ṣà ẹgbẹdọgbọ̀n ọkunrin ninu wọn li opópo; nwọn lepa wọn kikan dé Gidomu, nwọn si pa ẹgba ọkunrin ninu wọn.

46. Bẹ̃ni gbogbo awọn ni o ṣubu ni ijọ́ na ninu awọn ara Benjamini jẹ́ ẹgba mejila ọkunrin o le ẹgbẹrun ti o nkọ idà; gbogbo awọn wọnyi li akọni ọkunrin.

A. Oni 20