31. Awọn ọmọ Benjamini si jade tọ̀ awọn enia na lọ, a si fà wọn kuro ni ilu; nwọn si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn enia, nwọn npa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju; li opópo wọnni ti o lọ si Beti-eli, ati ekeji si Gibea, ni pápa, nwọn pa ìwọn ọgbọ̀n ọkunrin ninu Israeli.
32. Awọn ọmọ Benjamini si wipe, A lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli wipe, Ẹ jẹ ki a sá, ki a si fà wọn kuro ni ìlú si opópo.
33. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si dide kuro ni ipò wọn, nwọn si tẹ́gun ni Baali-tamari: awọn ti o wà ni ibuba ninu awọn enia Israeli si dide kuro ni ipo wọn, lati pápa Gibea wá.
34. Ẹgba marun ọkunrin ti a ti yàn ninu gbogbo Israeli si lọ si Gibea, ìja na si le gidigidi: ṣugbọn nwọn kò si mọ̀ pe ibi sunmọ wọn.
35. OLUWA si kọlù Benjamini niwaju Israeli: awọn ọmọ Israeli si pa ẹgba mejila ọkunrin o le ẹdẹgbẹfa li ọjọ́ na ninu awọn enia Benjamini: gbogbo awọn wọnyi li o kọ́ idà.
36. Bẹ̃li awọn ọmọ Benjamini wa ri pe a ṣẹgun wọn: nitoriti awọn ọkunrin Israeli bìsẹhin fun awọn ara Benjamini nitoriti nwọn gbẹkẹle awọn ti o wà ni ibùba, ti nwọn yàn si eti Gibea.
37. Awọn ti o wà ni ibùba si yára, nwọn rọ́wọ̀ Gibea; awọn ti o wà ni ibuba si papọ̀, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu na.
38. Njẹ àmi ti o wà lãrin awọn ọkunrin Israeli, ati awọn ti o wà ni ibùba ni pe, ki nwọn jẹ ki ẹ̃fi nla ki o rú soke lati ilu na wá.
39. Nigbati awọn ọkunrin Israeli si pẹhinda ni ibi ìja na, Benjamini si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn ọkunrin Israeli, o si pa bi ọgbọ̀n enia: nitoriti nwọn wipe, Nitõtọ a lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìja iṣaju.
40. Ṣugbọn nigbati awọsanma bẹ̀rẹsi rú soke lati ilu na wá pẹlu gọ́gọ ẹ̃fi, awọn ara Benjamini wò ẹhin wọn, si kiyesi i, ẹ̃fi gbogbo ilu na gòke lọ si ọrun.
41. Awọn ọkunrin Israeli si yipada, awọn ọkunrin Benjamini si damu: nitoriti nwọn ri pe ibi déba wọn.
42. Nitorina, nwọn pẹhinda niwaju awọn ọkunrin Israeli si ọ̀na ijù; ṣugbọn ogun na lepa wọn kikan; ati awọn ti o ti ilu wọnni jade wá ni nwọn pa lãrin wọn.
43. Bẹ̃ni nwọn rọgba yi Benjamini ká, nwọn lepa wọn, nwọn tẹ̀ wọn mọlẹ ni ibi isimi, li ọkankan Gibea si ìha ila-õrùn.