31. Awọn ọmọ Benjamini si jade tọ̀ awọn enia na lọ, a si fà wọn kuro ni ilu; nwọn si bẹ̀rẹsi kọlù ninu awọn enia, nwọn npa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju; li opópo wọnni ti o lọ si Beti-eli, ati ekeji si Gibea, ni pápa, nwọn pa ìwọn ọgbọ̀n ọkunrin ninu Israeli.
32. Awọn ọmọ Benjamini si wipe, A lù wọn bolẹ niwaju wa, gẹgẹ bi ìgba iṣaju. Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli wipe, Ẹ jẹ ki a sá, ki a si fà wọn kuro ni ìlú si opópo.
33. Gbogbo awọn ọkunrin Israeli si dide kuro ni ipò wọn, nwọn si tẹ́gun ni Baali-tamari: awọn ti o wà ni ibuba ninu awọn enia Israeli si dide kuro ni ipo wọn, lati pápa Gibea wá.
34. Ẹgba marun ọkunrin ti a ti yàn ninu gbogbo Israeli si lọ si Gibea, ìja na si le gidigidi: ṣugbọn nwọn kò si mọ̀ pe ibi sunmọ wọn.
35. OLUWA si kọlù Benjamini niwaju Israeli: awọn ọmọ Israeli si pa ẹgba mejila ọkunrin o le ẹdẹgbẹfa li ọjọ́ na ninu awọn enia Benjamini: gbogbo awọn wọnyi li o kọ́ idà.
36. Bẹ̃li awọn ọmọ Benjamini wa ri pe a ṣẹgun wọn: nitoriti awọn ọkunrin Israeli bìsẹhin fun awọn ara Benjamini nitoriti nwọn gbẹkẹle awọn ti o wà ni ibùba, ti nwọn yàn si eti Gibea.
37. Awọn ti o wà ni ibùba si yára, nwọn rọ́wọ̀ Gibea; awọn ti o wà ni ibuba si papọ̀, nwọn si fi oju idà kọlù gbogbo ilu na.