2. Awọn olori gbogbo enia na, ani ti gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, si pésẹ̀ larin ijọ awọn enia Ọlọrun, ogún ọkẹ ọkunrin ẹlẹsẹ̀ ti o kọ idà.
3. (Awọn ọmọ Benjamini si gbọ́ pe awọn ọmọ Israeli gòke lọ si Mispa.) Awọn ọmọ Israeli si wipe, Sọ fun wa, bawo ni ti ìwabuburu yi ti ri?
4. Ọkunrin Lefi na, bale obinrin na ti a pa, dahùn wipe, Mo wá si Gibea ti iṣe ti Benjamini, emi ati àle mi, lati wọ̀.
5. Awọn ọkunrin Gibea si dide si mi, nwọn si yi ile na ká mọ́ mi li oru; nwọn si rò lati pa mi, nwọn si ba àle mi ṣe iṣekuṣe, o si kú.
6. Mo si mú àle mi, mo ke e wẹ́wẹ, mo si rán a lọ si gbogbo ilẹ-iní Israeli: nitoriti nwọn hù ìwakiwa ati ìwa wère ni Israeli.
7. Kiyesi i, ọmọ Israeli ni gbogbo nyin ṣe, ẹ mú èro ati ìmọran nyin wá.
8. Gbogbo awọn enia na si dide bi ọkunrin kan, wipe, Kò sí ẹnikẹni ninu wa ti yio wọ̀ inu agọ́ rẹ̀ lọ, bẹ̃ni kò sí ẹnikẹni ti yio pada si ile rẹ̀.
9. Ṣugbọn nisisiyi eyi li ohun ti a o ṣe si Gibea; awa ṣẹ keké, awa o si gòke lọ sibẹ̀;
10. Awa o si mú ọkunrin mẹwa ninu ọgọrun jalẹ ni gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli, ati ọgọrun ninu ẹgbẹrun, ati ẹgbẹrun ninu ẹgbãrun, lati mú onjẹ fun awọn enia na wá, ki nwọn ki o le ṣe, nigbati nwọn ba dé Gibea ti Benjamini, gẹgẹ bi gbogbo ìwa-wère ti nwọn hù ni Israeli.
11. Bẹ̃ni gbogbo ọkunrin Israeli dó tì ilu na, nwọn fi ìmọ ṣọkan bi enia kan.
12. Awọn ẹ̀ya Israeli si rán ọkunrin si gbogbo ẹ̀ya Benjamini, wipe, Ìwa buburu kili eyiti a hù lãrin nyin yi?