12. Awọn ẹ̀ya Israeli si rán ọkunrin si gbogbo ẹ̀ya Benjamini, wipe, Ìwa buburu kili eyiti a hù lãrin nyin yi?
13. Njẹ nisisiyi ẹ mu awọn ọkunrin na fun wa wá, awọn ọmọ Beliali, ti nwọn wà ni Gibea, ki awa ki o le pa wọn, ki awa ki o le mú ìwabuburu kuro ni Israeli. Ṣugbọn awọn ọmọ Benjamini kò fẹ́ fetisi ohùn awọn ọmọ Israeli awọn arakunrin wọn.
14. Awọn ọmọ Benjamini si kó ara wọn jọ lati ilu wọnni wá si Gibea, lati jade lọ ibá awọn ọmọ Israeli jagun.
15. A si kà awọn ọmọ Benjamini li ọjọ́ na, lati ilu wọnni wá, nwọn jẹ́ ẹgbã mẹtala ọkunrin ti nkọ idà, lẹhin awọn ara Gibea ti a kà, ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin.
16. Ninu gbogbo awọn enia yi, a ri ẹdẹgbẹrin àṣayan ọkunrin aṣòsi; olukuluku wọn le gbọ̀n kànakana ba fọnrán owu li aitase.
17. Ati awọn ọkunrin Israeli, li àika Benjamini, si jẹ́ ogún ọkẹ enia ti o nkọ idà: gbogbo awọn wọnyi si jẹ́ ologun.
18. Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si lọ si Beti-eli nwọn si bère lọdọ Ọlọrun, wipe, Tani ninu wa ti yio tètekọ gòke lọ ibá awọn ọmọ Benjamini jà? OLUWA si wipe, Juda ni yio tète gòke lọ.
19. Awọn ọmọ Israeli si dide li owurọ̀, nwọn si dótì Gibea.
20. Awọn ọkunrin Israeli si jade lọ ibá Benjamini jà; awọn ọkunrin Israeli si tẹ́gun dè wọn ni Gibea.
21. Awọn ọmọ Benjamini si ti Gibea jade wá, nwọn si pa ẹgba mọkanla enia ninu awọn ọmọ Israeli.
22. Awọn enia na, awọn ọkunrin Israeli si gbà ara wọn niyanju, nwọn si tun tẹ́gun ni ibi ti nwọn kọ́ tẹ́gun si ni ijọ́ kini.
23. (Awọn ọmọ Israeli si gòke lọ, nwọn si sọkun niwaju OLUWA titi di aṣalẹ, nwọn si bère lọdọ OLUWA wipe, Ki emi ki o si tun lọ ibá awọn ọmọ Benjamini arakunrin mi jà bi? OLUWA si wipe, Ẹ gòke tọ̀ ọ.)