4. Ṣugbọn baba ati iya rẹ̀ kò mọ̀ pe ati ọwọ́ OLUWA wá ni, nitoripe on nwá ọ̀na lati bá awọn Filistini jà. Nitoripe li akokò na awọn Filistini li alaṣẹ ni Israeli.
5. Nigbana ni Samsoni sọkalẹ lọ si Timna, ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀, o si dé ibi ọgbà-àjara ti o wà ni Timna: si kiyesi i, ẹgbọrọ kiniun kan nke ramuramu si i.
6. Ẹmi OLUWA si bà lé e, o si fà a ya bi iba ti fà ọmọ-ewurẹ ya, bẹ̃ni kò sí nkan li ọwọ́ rẹ̀: on kò si sọ fun baba tabi iya rẹ̀ li ohun ti o ṣe.
7. On si sọkalẹ lọ, o si bá obinrin na sọ̀rọ; on si wù Samsoni gidigidi.
8. Lẹhin ijọ́ melokan o si tun pada lati mú obinrin na, o si yà lati wò okú kiniun na: si kiyesi i, ìṣu-ọ̀pọ oyin wà ninu okú kiniun na, ati oyin.
9. O si bù ninu rẹ̀ si ọwọ́ rẹ̀, o si njẹ ẹ li ajẹrìn, titi o si fi dé ọdọ baba ati iya rẹ̀, o si fi fun wọn, nwọn si jẹ: ṣugbọn on kò sọ fun wọn pe ninu okú kiniun li on ti mú oyin na wá.
10. Baba rẹ̀ si sọkalẹ tọ̀ obinrin na lọ: Samsoni si sè àse nibẹ̀; nitoripe bẹ̃li awọn ọmọkunrin ima ṣe.
11. O si ṣe nigbati nwọn ri i, nwọn si mú ọgbọ̀n enia wa bá a kẹgbẹ.
12. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ jẹ ki npa alọ́ kan fun nyin: bi ẹnyin ba le já a fun mi titi ijọ́ meje àse yi, ti ẹnyin ba si mọ̀ ọ, njẹ emi o fun nyin li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ:
13. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba le já a fun mi, njẹ ẹnyin o fun mi li ọgbọ̀n ẹ̀wu, ati ọgbọ̀n ìparọ aṣọ. Nwọn si wi fun u pe, Pa alọ́ rẹ ki awa ki o gbọ́.