1. AWỌN ọkunrin Efraimu si kó ara wọn jọ, nwọn si kọja si ìha ariwa; nwọn si wi fun Jefta pe, Ẽṣe ti iwọ fi rekọja lati bá awọn ọmọ Ammoni jà, ti iwọ kò si pè wa ki awa ki o le bá ọ lọ? awa o fi iná kun ile rẹ mọ́ ọ lori.
2. Jefta si wi fun wọn pe, Emi ati awọn enia mi ti mbá awọn ọmọ Ammoni jà gidigidi; nigbati emi kepè nyin, ẹnyin kò si gbà mi li ọwọ́ wọn.
3. Nigbati emi si ri pe ẹnyin kò gbà mi, mo fi ẹmi mi wewu, emi si rekọja sọdọ awọn ọmọ Ammoni, OLUWA si fi nwọn lé mi li ọwọ́: nitori kini ẹnyin ha ṣe gòke tọ̀ mi wá li oni, lati bá mi jà?
4. Nigbana ni Jefta kó gbogbo awọn ọkunrin Gileadi jọ, o si bá Efraimu jà: awọn ọkunrin Gileadi si kọlù Efraimu, nitoriti nwọn wipe, Isansa Efraimu li ẹnyin ara Gileadi iṣe, lãrin Efraimu, ati lãrin Manasse,