9. Awọn ọmọ Ammoni si gòke odò Jordani lati bá Juda jà pẹlu, ati Benjamini, ati ile Efraimu; a si ni Israeli lara gidigidi.
10. Awọn ọmọ Israeli si kepè OLUWA wipe, Awa ti ṣẹ̀ si ọ, nitoriti awa ti kọ̀ Ọlọrun wa silẹ, a si nsín Baalimu.
11. OLUWA si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Emi kò ti gbà nyin kuro lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ awọn ọmọ Amori, ati lọwọ awọn ọmọ Ammoni, ati lọwọ awọn Filistini?
12. Awọn ara Sidoni pẹlu, ati awọn Amaleki, ati awọn Maoni si ti npọ́n nyin loju; ẹnyin kepè mi, emi si gbà nyin lọwọ wọn.
13. Ṣugbọn ẹnyin kọ̀ mi silẹ, ẹ si nsìn ọlọrun miran: nitorina emi ki yio tun gbà nyin mọ́.
14. Ẹ lọ kigbepè awọn oriṣa ti ẹnyin ti yàn; jẹ ki nwọn ki o gbà nyin li akokò wahalà nyin.
15. Awọn ọmọ Israeli si wi fun OLUWA pe, Awa ti ṣẹ̀: ohunkohun ti o ba tọ́ li oju rẹ ni ki o fi wa ṣe; sá gbà wa li oni yi, awa bẹ̀ ọ.
16. Nwọn si kó ajeji ọlọrun wọnni ti o wà lọdọ wọn kuro, nwọn si nsìn OLUWA: ọkàn rẹ̀ kò si gbà òṣi Israeli mọ́.
17. Nigbana ni awọn ọmọ Ammoni kó ara wọn jọ nwọn si dó si Gileadi. Awọn ọmọ Israeli si kó ara wọn jọ, nwọn si dó si Mispa.
18. Awọn enia na, awọn olori Gileadi si wi fun ara wọn pe, ọkunrin wo ni yio bẹ̀rẹsi bá awọn ọmọ Ammoni jà? on na ni yio ṣe olori gbogbo awọn ara Gileadi.