A. Oni 1:18-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Juda si kó Gasa pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Aṣkeloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Ekroni pẹlu àgbegbe rẹ̀.

19. OLUWA si wà pẹlu Juda; o si gbà ilẹ òke; nitori on kò le lé awọn enia ti o wà ni pẹtẹlẹ̀ jade, nitoriti nwọn ní kẹkẹ́ irin.

20. Nwọn si fi Hebroni fun Kalebu, gẹgẹ bi Mose ti wi: on si lé awọn ọmọ Anaki mẹtẹta jade kuro nibẹ̀.

21. Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni.

22. Ati awọn ara ile Josefu, awọn pẹlu si gòke lọ bá Beti-eli jà: OLUWA si wà pẹlu wọn.

23. Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.)

24. Awọn amí na si ri ọkunrin kan ti o ti inu ilu na jade wá, nwọn si wi fun u pe, Awa bẹ̀ ọ, fi ọ̀na atiwọ̀ ilu yi hàn wa, awa o si ṣãnu fun ọ.

A. Oni 1