10. Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ.
11. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan.
12. Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ, nítorí pé o jẹ́ ọ̀dọ́. Ṣugbọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn onigbagbọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, ati ninu ìṣe rẹ, ninu ìfẹ́, ninu igbagbọ ati ninu ìwà pípé.