Timoti Keji 2:4-6 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Kò sí ọmọ-ogun tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ tí ó gbọdọ̀ tún tojú bọ àwọn nǹkan ayé yòókù. Àníyàn rẹ̀ kanṣoṣo ni láti tẹ́ ọ̀gágun rẹ̀ lọ́rùn.

5. Kò sí ẹni tí ó bá ń súré ìje tí ó lè gba èrè àfi bí ó bá pa òfin iré ìje mọ́.

6. Àgbẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ lóko ni ó kọ́ ní ẹ̀tọ́ sí ìkórè oko.

Timoti Keji 2